Ìjoba Ìbilẹ̀ Ifako-Ijaiye ní Ìpínlẹ̀ Èkó lójóo ìşęgun ọjọ kejìdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2023 ti fi kún akitiyan rè láti ṣètò ohun amáyé-tura fún àwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ òun nípa ṣíṣe àgbékalè ètò títa àwọn èròjà oúnjẹ ní èdínwó.
Ètò èròjà oúnjẹ títa ní èdínwó yìí tó wáyé ní olú iléeşé ìjọba ìbílẹ̀ òun gẹgẹbí àtèjade láti ọ̀dọ̀ akòwé Ìròyìn sì alága Káńsù, Alagba Salaam Lateef ni láti fí kún akitiyan ìjọba ìbílẹ̀ Ifako-Ijaiye lábé Omooba Usman Akanbi Hamzat láti mú àdínkù bá ìnira tí àwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ òun ń dojúkọ látàrí àyokúrò owò orí epo ròbì tó wáyé láìpé yìí láti Ọwọ́ Ìjọba àpapò lábẹ́ Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ́bí Ààrẹ.
Ẹ ó rántí pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nínú ọ̀rọ̀ àkóso rẹ ní ọjọ́ ìbúra kéde pé ìjọba òun ti yọ èkúnwo tí ìjọba àpapò ń ṣàn lórí owó epo kúrò, èyí tí ó ti ń mú èkúnwo àti èlé wá fún iye tí an ra jáálá epo. Ní kówó-kówó ni èyí sì fa èlé to pò bá iye tí a n ra àwọn nǹkan ní ọjà káàkiri orile-ede yii, paapaa, àwọn ohun jíjẹ. Látàrí ìdí èyí, ìnira ńlá lọ tí ń bá àwọn ọmọ Naijiria fínra. Ìdí nìyí tí ìjọba Tinubu fi ń sakitiyan lati ṣètò iranwo fún àwọn ènìyàn orile-ede yii, paapaa julo, pelu eedegbeta billionu (₦500B) ti o ti jẹ́ yiya soto fún ìtura awon omo ile Naijiria. Aàrẹ ko wa sa i képe ìjọba Ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan láti ṣe àgbékalè irufẹ ètò òun láti mú ara de àwọn ènìyàn tí wọn náà.
Èyí ló mú kí ìjọba Omooba Usman Akanbi Hamzat ṣe àgbékalè ètò títa àwọn èròjà oúnjẹ l'edinwo ní olú iléeşé ìjọba ìbílẹ̀ òun ní ọjọ ìṣégun tó kọjá yìí. Aṣọjúkò iléeşé wá níbi ètò òun ṣàlàyé pé ẹgbẹ̀rún kan náírà ní wọn ta iṣu ńlá kan, bee naa si ni kíréétìì ẹyin kan. agolo derika ìresi márùn-ún ni wón ta ní ẹgbẹ̀rún kan náírà péré pelu agogo derika gàárì márùn-ún tí òun náà je títa ní ẹgbẹ̀rún kan náírà.
Àwọn nkan yòókù tí wọn ta ní owó pònto ní òróró, epo-pupa àti Indomie.