E DÚRÓ DÉÉDÉ KÍ E SI MÁ GBÒJÈGÉ FÚN ÀWỌN ELÉGBÒ IGI OLÓRÓ, ÒGÁGUN-FÈYÌNTÌ MARWA PÀṢẸ FÚN ẸGBERUN MÉJÌ ÀBÒ AKẸKOO JADE OSISE OLOGUN TUNTUN AJO NDLEA
Ile eko àjọ NDLEA ni Katsina ṣayẹyẹ ikekoo jáde fún àwọn àsèsèwón oloogun àjọ òun tuntun


Ògágun-fèyìntì Buba Marwa tí ó jé olùdarí àgbà fún àjò tí ó ń gbógun ti gbígbé, títà àti àsìkò oògùn olóró ni ilẹ̀ Nàìjíríà tí pàṣẹ fún àwọn àsèsèwón àjọ òun tí wọn ṣe ayẹyẹ ìkékòó jáde fún ní ọjọ ni òní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹwàá ọdún 2023 ni ilu Katsina láti dúró déédéé, kí wọn má gbojege, bẹẹ kí wón sì sá fún gbígba kobe lowo awon ti n sowo egbògi oloro ni ilẹ̀ yí, kí akitiyan igbogun tí títà, gbígbé àti àsìkò egbògi olóró nileyi ó lè kesejaari.

Ògágun-fèyìntì Buba Marwa, Oga agba àjọ NDLEA

Oga àjọ NDLEA òun ti olùbádámòràn pàtàkì rè, Ogagun-feyinti, Col Yakubu Bako (RTD) soju fún fi yẹ àwọn asesewon osise àjọ òun pé kí wọn ó rántí pé bí won o bá mú isẹ won bii ise, tàbí bi wón bá gbàbòdè fún àwọn oloogun oloro, yio mu àkùdé àti ewu ńlá bá àwùjo, èyí ti ko ni sàì ní ipa buruku lori ẹbí enikookan won.

Olùbádámòràn pàtàkì fún oga agba àjọ NDLEA, Ògágun-fèyìntì Yakubu Bako níbi ayẹyẹ oun

Ogagun òun kò sàì ro awon asesewon osise ológun àjọ Òun láti ríi pé wọn kò tapo sì ààlà àjọ òun, bee ni wón kó bá orúkọ rere àti àkọsílẹ̀ rere tí àjò òun ni je, àmọ, bí ààyè tí sì sílè fún wọn yìí, kí wọn ó lọọ láti fí ipa tí wọn ti isẹ rere àjọ òun síwájú sii.


Ninu oro rẹ, Ogagun Marwa fi kún pé, ipo to lápere ni àṣeyọrí ìjà àjọ òun lòdì sí isẹ gbígbé, títà àti lílọ oògùn olóró wá. Nitorinaa, àwọn asesewon osise ológun òun ni àjọ òun gbekele láti àṣeyọrí sii ju ti àtèyìnwá lọ.
Ogagun òun kò sàì wá fi dá àwọn osise ológun òun lójú pé isẹ to ni laada tí ó sì ní iyì ni isẹ won nítorí ipa pataki ni isẹ àjọ òun ń kó lawujo láti jẹ ki àwùjo ó wà láàárín. Nitorinaa, àwọn osise òun gbodo jìnà sì riba gbigba àti gbogbo ohun tó jemo ìwà ibaje.

Ìdíje Títọ eya ara ìbon pò fún àwọn àsèsèwón oloogun àjọ NDLEA

Yiyan bí ologun àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde tuntun àjọ NDLEA

Sise Àfihàn ẹ̀kọ́ nípa àgbékalè ètò ìjà bo ba dogun

Ogagun Marwa wàá fi dá àwọn asesewon osise ológun òun lójú wípé àwọn ohun èlò irinse ìgbàlódé to bá òde òní mu pelu ìmò ẹ̀rọ ni àjọ òun yio lọ láti máa fi dojúkọ ìwà gbígbé, títà àti lílọ egbògi olóró. Ogagun Marwa kò wá sàì ro awon oniroyin àti gbogbo àwùjọ láti kún wọn lọ́wọ́ kí ìwà ibi yìí, tí ó ń yọ àwùjo wá lenu ó ké lọ sokun ìgbàgbé tàbí kí ó dínkù pátápátá.
Ní ikadii, Ògágun-fèyìntì Marwa fi ìmoore hàn sí gbogbo àwọn tí wón kún wọn lọ́wọ́ láti jé kí eko àwọn àsèsèwón oloogun àjọ òun ó kesejaari. Pàápàá, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Katsina àti Emir ìlú Katsina, Abdullahi Kabir Usman pelu àwọn ènìyàn ìlú òun, awon osise ati alase ajo Oju-Lalakan-fii-Sori ile Naijiria, NSCDC, pelu awon alase àti oluko ni ile-eko àjọ NDLEA to wá ní ìlú Katsina.

Àwon ètò tó wáyé nibi ayẹyẹ ikekoo jáde òun ni yíyàn bí ológun, lílọ ìdíje lílọ àwọn ohun ìjà ogún àti àwọn ètò míràn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *