ÌJỌBA MI YÓÒ MÚ ỌDÚN ÌBEJÌ TI IGBÓ-ORÀ GBÒÒRÒ SII.
Gomina Seyi Makinde ṣèlérí ìgbélárugẹ fún ọdún ibojì ni Igbo-Ora


Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Alagba Seyi Makinde tí ṣèlérí wípé ijoba òun yóò fowó sowopo pelu àwọn pẹ̀lú àwọn ènìyàn Igbó-Orà láti fẹ ỌDÚN ÌBEJÌ tí wón máa ń ṣe ní ìlú òun kí ọdún òun lè gbòòrò síi.


Gómìnà ṣèlérí yìí níbi ọdún ÌBEJÌ tí wọn máa ń ṣe ní ọdọọdún ni ilu igbo-ora lapaa Oke-ògùn, Ìpínlè Oyo. Ọdún ibeji je ọdún ìbílẹ̀ ni ilu igbo-ora tí ìjọba fowó síi láti sagbateru fún ní àgbègbè òkè ogún.


Gẹ́gẹ́bí Gómìnà ti rán àwọn ènìyàn létí, igun márùn-ún ni ìjọba pín Ìpínlè Ọ̀yọ́ sì, igun kookan lọ sí ní irufẹ ọdún ìbílè tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fowó síi láti sagbateru fún. Fún igun oke-ogun, ọdún ibeji ilu igbo-ora ní ìjọba fowosii. Ìdí nìyí tí Gómìnà Seyi Makinde fi ṣe ìlérí láti sise pò pẹ̀lú àwọn tó ń sagbekale ọdún ibeji láti kún wọn ní owó kí ọdún òun lè fojú síi, kí ó sì gbòòrò síi.


Níbi ọdún òun to wáyé laipe yìí, oríṣi àwọn ohun tó jẹ́ mọ àṣà àti ìṣe ilé Yoruba, pàápàá, tí ilu igbo-ora àti òkè lápapọ̀ lọ farahàn bíi, ìjọ jíjó, oúnjẹ, aṣọ ìbílè, ìpohùnréré, orin kiko àti beebee lọ. Apá ọdún òun to ṣe pàtàkì jù ni àfihàn àwọn ibeji ní ìlú òun.
A ó rántí pé oruko ilu Igbó-Orà tí wó ìwé àjò "Guiness World Record" bi ilu ti wọn ti ń ní iye ibeji to pò julo ní gbogbo agbaye. Bẹ́ẹ̀ Yoruba bò, wọn ní, na-an ní,nà-an ní, ohun àní làá ná-àn ní, bí ọmọ Asegita tíì ná-án ní èpò igi. Ohun tí ilu Igbó-Orà ní ní wọn ń na-an ní, ìdí nìyí tí ilu òun fi máa ń ṣe ọdún ibeji Gẹ́gẹ́bí ọdún ìbílẹ̀ ilu òun lodoodun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *