Òrò ijangbara àwọn ẹ̀yà Igbo, iyùn àwọn Biafra máa tí to ohun tí a n sàpérò lé lórí, kí á má pèé ní gbígbó ajá lásán nítorí ó waa dá bí i pé ajá òun ti wá fẹ́ di dìgbòlugi báyìí.
Ìdí tí ọ̀rọ̀ àwọn alakatakiti biafria fi gba amojuto ni pé, bí a kò bá tètè Pa ékan ìrókò, kí Olúwéré ó máa lọ máa béèrè ẹbọ. Ihale àwọn tó ń ṣe kokari yiyapa àwọn ẹ̀yà igbo kúrò ní orileede yí tí ń lé kénka, o sì to ohun tí a a bójú tó.
Bẹẹ, ọ̀rọ̀ arákùnrin Simon Ekpa, ọmọ ilẹ̀ Igbo to fi ilẹ Finland ṣe ibùgbé ń fẹ́ àbójútó pẹ̀lú, nítorípé, ọkùnrin yìí, tí ń pè ara rẹ ní olootu ilé Biafra ní ń gbé ìta soko sínú ilé, ọkọ òun sì ti béèrè sì ní máa dùn lórí òrùlé Naijiria bayii pẹ̀lú bí ọkùnrin òun àti àwọn kan ṣe kéde òmìnira ilé biafria, laibesubegba, lai rántí bí irú ìkéde bẹ́ẹ̀ ṣe fa ogun abele to jà ní orílè-èdè yí laarin 1967 sì 1970.
Simon Ekpa níbi apero Biafra ní Orileede Finland
Ẹ ó rántí pé ní ose to kọjá ní awon omo ẹ̀yà igbo péjọ sì gbongan kan ni ilu Finland níbi tí wọn ti sàpérò lórí yiyapa ẹ̀yà òun kúrò lára Nàìjíríà. Níbi apero òun gan ni won tí kéde òmìnira ilé igbo lakotun.
Lóòótọ, èrín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Naijiria ń fi wọn rìn, nítorí, lójú wọn, ewúré kan ń fèse hale ní, kò sì ohun tí yóò fi olówó ẹ ṣe. Sugbon awon ìṣẹ̀lẹ̀ ẹnu lóóló yìí ń fii hàn pé àwọn igbo yìí kò mú ọ̀rọ̀ òun ni kékeré rárá.
Lenu looto yìí ni Simon Ekpa fèsì sí ìlérí asoju ilé ọba UK ní orileede Nàìjíríà, Richard Montgomery. Asoju ile UK oun seleri laipe yii, pé ìlú UK yóò ran Naijiria lowo lati rii pe ilu oun tesiwaju lati wa ni eyokan soso. Itumo eyi ni pé bi eya kan ba gbe imu pé awon fe ya lọ, Ìlú UK se tan lati se iranwo lati ba iru eya bee ja. Eya igbo si ro pe, awon gan ni Asoju ilu UK oun n ba wi, ìdí nìyí tí Simon Ekpa sì fi fèsì.
Richard Montgomery, Aṣojú ilé UK ní Nàìjíríà
Ninu ihale Simon Ekpa, ó léèri pé tí ogún òun ba sele, àwọn yóò lè gbogbo asoju ilu òkèèrè dànù.
Ihale míràn tí Simon Ekpa tún ṣe ní ti ipinle Eko. Simon Ekpa leri lowolowo yìí, pé bí Ijoba Ipinle Eko kó bá yowó nínú títí ọjà tí àwọn ọmọ igbo, àwọn yóò gbé ogun dìde sí ipinle Èkó.
Gomina Ipinle Eko, Babajide Sanwolu
E o rántí pé ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó gbé àwọn ọjà kan tí ní Ìpínlẹ̀ òun laipe yìí. Lára wọn ni Ọjà Trade fair àti ti Ladipo. Àwọn ẹ̀yà igbo si ni o poju nínú àwọn tó ń tajú làwọn ọjà òun. Ìdí tí ipinle Eko sọ pé awon fi ti awon oja pa ni ìwà ohun àti ibaje pò ní àwọn ọjà òun. Àmọ́, kàkà kí Simon Ekpa ó bá àwọn èèyàn rẹ sọ̀rọ̀. Ihale ìjà ní o n kò balẹ̀.
Àwọn èèyàn wonyi ó sì yẹ ṣafihàn àwọn nkan ìjà ogun tí wọn ti ko jọ àti agbára omoogun wọn, Biafrian Liberation Army. Wọn ti ẹ máa ń fónnu pé àwọn ń borí ìjà tí àwọn omoogun ilé Naijiria ń bá won ja. Wọn ní bí owó ṣe ń wọn ẹṣin ní àwọn ń Pa omoogun ilé Nàìjíríà.
Àmọ́ sá, àgbàrá kò ní ohun ó ní ilé wo, onílé ní kò ní gbà fún. Ṣe ló yẹ kí ìjọba Ìlè Naijiria ó mú ọ̀rọ̀ Simon Ekpa àti àwọn akegbé rẹ ní òkú kúndùn.