ÌYANU ŃLÁ BÍ ÀGÀN ODÚN MÉÈDÓGBÒN SE BI ỌMỌ MẸSAN-AN LEKANSOSO
Obinrin àgàn olójó-pípé bí ọmọ mẹsan leekansoso


Iyalenu nla gba a loje bi obinrin agan kan se bi omo mẹsan leekansoso laipe yii ni ile iwosan.
Lóòótọ ni pé a-seyi-o-wu ni Ẹlẹ́dàá bí ó ti jẹ́ pé oríṣi ona ni ó máa ń gba láti fí ìṣe awamaridii àti ÌYANU rẹ hàn àwa ẹdá.


Tuntun tí eledua ṣe ní ti obìnrin Abileko ọmọ igbo kan tí orúkọ rẹ ń je Obianuju Anthonia Ibeanu ṣe bí ọmọ mẹsan an Lekan ṣoṣo leyin ti o ti yà àgàn fún ọdún meedogbon.


Gbogbo wa là mo pe ẹgan ńlá ní bí obìnrin bá yá àgàn ni àwọn ẹ̀yà ilé Afirika, paapaa julo, àwọn ẹ̀yà ilé Nàìjíríà. Ojú irú obìnrin bẹẹ a sì máa rí eemo. Bí oro abilóko yìí tí rí rẹ, tí ojú rẹ sì ti rí mabo gege bí ọ̀rọ̀ rẹ fún ọdún meedogbon.

Àmọ́ leyin ọdún meedogbon, Ọlọ́run gbó adua rẹ, o sì fi inú soyun. Gẹ́gẹ́bí obìnrin igbo yí tí sọ, ìyanu lọ je nígbà tí òun ṣàkíyèsí pé oyún tí dúró sí òun lára. Àmọ́, nígbà tí àwọn se àkíyèsí bí ikùn òun ti to, àwọn tí ẹ lérò pé ibeji ní yóò jẹ.

Sugbon, nigbati obìnrin yìí yọ ó robi, nise ni ó bere si ni yẹ ọmọ béèrè ẹ títí tí àwọn dókítà fi kaa pé mẹsan-an. Èyí fihan, looto, pe alágbára ni Ọlọ́run, kii sì yẹ fi hàn pé alágbára ni òun, àbí, boo ni inu obìnrin kan ṣoṣo ṣe gba ọmọ mesan-an leekansoso, tí mesesan sì jáde layo?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *