E MO WE OHUN TI KII SE TIWA MOWA LORUN O! AARE TINUBU KO LO FE LO OKO OJU OMI – AMUGBALEGBE AARE
Amugbalegbe Aare ni Omoogun Ori omi NAijiria lo fe ra oko oju omi onifaaji, kii se Aare Tinubu

 Amugbalegbe Aare Bola Ahmed Tinubu lori oro igbohun safefe, Tope Ajayi ti pa pariwo tantan ki awon omo ile Naijiria o ma we ohun ti kii se ti Aare Naijiri mo on lorun lori bi won ti se n gbe poyi enu pe Aare Tinubu lo beere fun Oko oju omi igbalode ti won saaba maa n fi gba faaji ori omi ti won n pe ni yatch ni ede geesi.

E o ranti pe Aare Tinubu ni lowolowo yii fi afikun eto isuna oni tirilionu meji le die ranse si ile igbimo asofin Naijiria fun ibuwolu, ninu eyi ti bilionu marun wa fun rira oko oju omi igbalode ti a so yii.

Lati igba ti eleyi si ti jade si igboro aye ni awon omo Naijiria ti n kun ti won si n bu enu ate lu Aare Tinubu pe se oko oju omi fun faaji ni nkan ti Tinubu n ro pelu oro aje ile yii to denu kole ti gbogbo nkan si polukumusu.

Amo Tope Ajayi,  ti waa bo si igboro lati fi ye awon omo ile Naijiria pe kii se Aare Tinubu lo beere fun oko oju omi oun, amo, ileese ologun oju omi ile yii lo beere fun oko oju omi oun. Alagba Ajayi salaye siwaju sii pe bii ogoji billionu le die ni owo ti omoogun ori omi ile yii ko ranse. owo yii si wa fun rira awon orisirisi oko, kiko ibudo won omoogun oun si ilu Lekki ati Epe ni Ipinle Eko.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *