ỌPÉ O! ILÉ ÌGBÌMÒ ASOJÚ-SÒFIN BÈRÈ AKITIYAN LÁTI FÚN ILÈ YORÙBÁ NÍ ÌPÍNLẸ̣̀ MÉTA TUNTUN


Yorùbá bọ̀, wọ́n ní bí ìṣẹ́ ò bá tòde ọ̀run wá, bí ènìyàn bá fi àádọ́ọ́ta ọdún gba ẹran sìn, ó ye kó ní ìyá ẹran.

Lẹyìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹyìn tí ìran Yorùbá ti n báwọn se ìjọba tiwantiwa ní ilẹ̀ Nàìjíríà, se lo dà bíi pé se ni àwọn ànfààní ìjọba ọun n fò wá tí àwọn apá ibòmíràn sì n sè yàlà yòlò pèlú ọrọ̀ àjùmọ̀ni wa. kódà, àwọn apá ilẹ̀ kan ti sọ ara wọn di asè-má-lù, ajá bàbá. Béè ṣe ni mùdùmúdùn ìjọba ọ̀un n rogún sí apà ibìkan tí àwọn apá ilẹ̀ Yoruba ati apá ilẹ̀ Naijiria yóku si n l'anu s'átégùn.


Pàápáà jùlọ, àwọn ònà tí apá ibì kan tá a mọ̀ tá ò gbọdọ d'árúkọ fi n fi búrédì kó wa l'omi ọbẹ̀ ni ti iye ìpínlẹ̀ tí wọn ní àti iye ìjọba ìbílẹ̀ tí wọn ní. Bó se jẹ́ pé awọn ni wọn ní ìpínlẹ̀ tó pọjù yìí, bẹ̀ awọn ni won n pín owó tó pọ̀ jùlọ, bótiìjé pé ọ̀pọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ oun o ti ẹ̀ tó ìjọba ìbílẹ̀ míràn ní apá ilẹ̀ Yorubá.


Àmó sá o, ìgbà rere náà n bọ̀ nílẹ̀ Oòduà bí àwọn ìgbìmọ̀ Asoju-sofin se bẹ̀rẹ̀ akitiyan láti sèdá awọn Ìpínlẹ̀ mẹ́ta kan: ìpínlẹ̀ Ifẹ̀-Ìjẹ̀ṣa láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Ìpínlẹ̀ Òkè-Ògùn láti ara Ìpínlẹ̀ Òyó àti Ìpínlẹ̀ Ìjẹ̀bú láti ara Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Olùgbòwọ́ àbá ọ̀ún ní ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin ni Asòfin Olúwolé Ọ̀kẹ́ tó n sojú agbègbè Obòkun/Oríadé. Bí àbá yìí bá wolé tan, a jépé ilẹ̀ Yorùbá yóò di apá ilẹ̀ Naijiria to ni ipinle ju, bẹ̀ẹ́ sì ni mùdùnmúdùn ìjọba ti yóò máa wọ ilẹ̀ Yorubá yóò pọ si. Ní pàtàkì jùlọ̀, ìjọba yoó túnbọ́ súnmó awọn ènìyàn síi. A j ẹ́ pé ayé dáa dé síi fún ilẹ̀ Yoruba nìyẹ̀n.

Hónórébù Olúwolé Ọ̀kẹ́ tó n sojú agbègbè Obòkun/Oríadé ní Ile ìgbìmọ̀ Asojú-sòfin fún agbègbè Obòkun/ Oríadé, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì kí á yáa ké gbàjarè sí gbogbo asofin ọmọto Yoruba to wá nílé asòfin kéreré ati agba kí wọ́n le ti àbá yìí lẹ́yìn kí ó lẹ̀ jọ bọ̀rọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *