Ọjọ́ burúkú eṣù-gbomi-mu gbáà ní ọjọ́ọ́rú ọjọ́bọ to kọja ní ilèèwé giga TASUED ní Ijẹbú Ode ati ninu ayé àwọn ìdílé Fábìyí tó jé akẹ̀ẹ̀kọ̀ọ́ onípele tó gbẹ̀yìn ileewe ọ̀ún.
Gẹgẹ ìròyìn tí a kó jọ, awọn ọmọ ẹgbẹ òkùnkùn tí wọn fura sí kan, ló ṣe ikú pa Ahmed Àyìnlá Fábiyì, tí ń ṣe ọmọ onípele kẹrin ni ilé-ìwé gíga Tai Solarin University of Education (TASUED), Ìjagun, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀ ní agogo mẹta lọjọ Ọjọrú tó kọjá yíì. Ọjọ yìí gan-an ni Fábiyì ń ṣe ayẹyẹ ọjọ-ìbí rẹ̀ tí ó sì ń gbaradì láti ṣe àṣekágbá ìdánwò, kí àwọn géńdé ọkùnrin ẹlẹgbẹ́ òkùnkùn tó wá tàn án kúrò nínú gbòngán ìdánwò ní ọjọ kẹ̀ta, oṣù kèje, ọdún 2024.
Ṣé Pánsá ò fura, pánsá já síná, ajá ò fura, àjá jìn, àwọn ọkùnrin yìí fi ara han Fábiyì gẹgẹ́ bí ọ̀rẹ rẹ̀, wọn sì ni àwọn ní ẹ̀bùn ìjọnilójú fún-un, kí ó tẹ̀lé àwọn ká lọ, láì mọ̀ wí pé ọgbón àti dá ẹ̀mí òun légbodò ni.
A kò mọ èyíkéyìí nínú àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọn ṣe iṣẹńlá ibi yìí, ṣùgbón agbègbè Ìdánilẹkọ̀ọ́ éka ìmọ̀-ẹ̀rọ ni wọn pa olóògbé Fábiyì sí. Ẹ̀kọ nípa ìtàn àti Ìbára-eni-sepo-lọ́rọ̀-ilẹ̀-òkèrè, History and Diplomatic Studies, ni ó sì ń kọ nílé èkọ́ gíga náà.
Ahmed Fabíyìí, akekọ̀ọ́ TASUED tí wọ́n sá pa
Nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti fojú hàn ni Alukoro ilé-ìwé náà, tí ń ṣe ìyáàfin Ayọ̀túndé Odubela sọ pé, “Èròńgbà àwọn oníṣẹ ibi yìí farahàn nígbà tí wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní fa Fábiyì lọ sínú igbó kan tó wà lágbègbè Ìdánilẹkọ̀ọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ tí Fásitì náà. Inú igbó yìí ni wọn sì ti lùú bíi bàrà, kí wọn tó ṣa pa.
Ó ní, ní tòótọ ni wọn tan ọmọ ilé-ìwé náà jáde ní gbòngàn bí ẹni pé wọn ń ṣe ayẹyẹ nítorí Ọjọbọ̀ òun gan-an ni ọjọ-ìbí rẹ̀.
Gbogbo ènìyàn ló rò pé ayẹyẹ rẹ̀ ni wón ń ṣe, à fi ìgbà tí wọn fà á lọ sí inú igbó lọ pa.
Bótìlẹ̀jẹ́ wípé awọn tó rí olóògbé nígbà tí wọn n fáà lọ ké gbàjárè sí àwọn òsììsẹ́ alààbò ilé-ìwé náà láti wá wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ṣùgbón nígbà tí àwọn ọ̀daràn ọmọ ẹgbẹ ẹgbẹ́ òkunkùn yìí rí pé, àwọn aláààbò ilé-ìwé náà ń bọ̀ lọdọ̀ àwọn, wón fẹsẹ̀ fẹ, wón sì sá lọ. Nígbà tí àwọn òsìṣé aláábò ọ̀ún yóò sì fi dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọn ti lú ú gan-an, wọn sì ti fi àdá dábírà sí i lára. Àwọn yìí du Fábiyì dìgbà-dìgbà, wọn sì gbé e lọ si ilé-ìwòsàn inú ọgbà náà níbi tí wọn ti dá wọn lóhùn lẹsẹkẹsẹ kí wọ́n tó tọka rẹ̀lọ sí ilé-ìwòsàn gbogbogbò ti Ìjẹbú-Òde ní kíákíá.
Àmó, ibi tí wọn ṣe Fábíyíì léṣe dé, ilé-ìwòsàn gbogbogbò Ìjẹ̀bú Òde kò lágbára láti toju re, nítorí se ni ilé ìwòsàn ọ̀ún tún tọka rẹ̀sí ilé ìwòsàn Fásitì Babcock. Ṣùgbọ́n, ó ṣeni láàánú pé arákùnrin Ahmed Àyìnlá Fábiyì gbé ẹmí mì kí ó tó dé ile-ìwòsàn yìí gẹgẹ́ bí arábìnrin Ayọtúndé Odubela ṣe sọ.
Àmọ́ sá, àwọn aṣojú ilé-ìwé náà ni pé, àwọn tí kan sì àwọn ọlọpàá nípa ìṣẹlẹ náà. Àwọn sí ti ṣe òfin pé, kò ní sí ayẹyẹ kankan nínú ọgbà ilé-ìwé Tasued mọ́, ayafi èyí tí àwọn bá lọwọ́ sí. béẹ̀ ni wọ́n ti sì dá ìdánwò ileewé náà dúró fún ìgbà díẹ.
Wàyí o, awọn ọlọpàá ti fi ọkàn iléèwè ọ̀ún àti awọn ebí oloogbé balẹ̀ pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lorí ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀un, àwọn sì ti ń kó àwọn afura si ẹlẹgbẹ òkùnkùn àgbègbè náà.
Ní èrò ilẹ́esẹ́ wa ẹ̀wẹ̀, a ò lérò pé ó yẹ kí irú nǹkan bayìí máa ṣẹlẹ nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ọ̀un pẹlú akitiyan awọn alásẹ ileewé TASUED latẹyìn wá, pàápàá, lásìkò ìdánwò, nítorí àsìkò ìdánwò gan ló yẹ kí ààbò inú ọgbà ilé-ìwé tún bọ̀ pọ̀ si.
Nítorí na, o yẹ kí ilé ẹ́kọ́ giga TASUED jáwé sóbì etò ààbò ilé-ẹ̀kọ́ ọ̀ùn. O yẹ ki awọn ẹ̀rọ ayáwòrán àìrí wà níbi gbogbo nínú ọgbà láti mọ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà náà.
Tẹni tó dé là rí, a ò mọ tẹnì tó ń bọ̀ lẹyìn. Ààbò tó péye ṣe kókó, ó ṣe pàtàkì ní ìlú, inú ọgbà ilé-ìwé àti níbi gbogbo. Nítorí ojú ni alákàn fí ń ṣọ́rí.
Nínú ìròyìn ìsẹlẹ̀ míran ẹ̀wẹ̀, awọn afurasí ẹlẹgbẹ̀ òkùnkùn tún ti ṣekú pa okunrin kan tí ìnagijẹ rẹ n jẹ́ "Big Sam" ni agbègbè Ìjọrá. Okunrin yìí tí awọn ènìyàn ní ó jẹ́ ògbóntagìrì ọmọ ẹgbẹ okùnkùn Ẹyẹ ni awọn tí wọn fura sí bí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Àyèé sekú pa ní adugbò rẹ̀ ní òpópónà Ìrètí ní Ìjọrá.
Dájádájú, ọrọ àwọn ọmẹẹgbẹ́ òkùnkùn tí wón n dá ẹ̀mí ara won légbodo loorèkóórè yii n fé amojuto ijọba ati gbogbo araalu o, nítorí pe ai ní mariwo Pààká, ó tó apéwò gbogbo ọmọ eríwo.
Gbogbo ẹni bímọ kó tọ, Èdùmàrè ò ní jẹ a fi ọju sunkún ọmọ.
Èdùmàrè á ma fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́wa
Amín o