ÌWỌ́DE ỌJỌ́ KÍNNÍ OṢÙ KẸJỌỌ NÍ ILẸ̀ NAIJIRIA, ELERU TÚN FẸ́ SUN’GI
Láti ọwọ́ Arowoogun Abiọla Ade-Ire. Njẹ́ nkan ò tún ní yan ní ile Naijiria pẹ̀lú iwọ́de ọjọ́ kííní oṣù kẹ́ẹ́jọ tí awọn kan tún gbeero.


Yorùbá bọ̀, wọ́n ní bí kò bá ṣeni rí, a kìí pé o tún dé. aṣamọ̀ yí ló dálé orí ìwọde tí awọn kan n gberò rẹ ní ọjọ́ kínní oṣù kẹ́jọ tó n bọ̀ yìí.


Sé ẹ ó rantí pe kẹrẹ kẹrẹ bí ipolongo iwọ́de oṣù kẹ́wàá ọdun 2020 ṣe bẹ̀ẹ̀rẹ̀ nìyìí tí a rò pé òwè lásán lọrọ nàá yoo jẹ̀, amọ́ tí o lọ ní aró nínú. Ìṣekúṣe tí awọn ọlọpàá, pàápàá awọn ẹ̀yà kan tí won n pè ni SARS ni awọn ọdọ́ ní awọ́n ní àwọ́n fẹ́ wọ́de takò. Bí wọn se bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe ara wọn re e, tí ìpòlongo ìwọ́de yìí gba ori gbogbo ojú opó ìbáraẹni-dọ́rẹ̀ẹ́ kan lóríi intánẹẹ́tì. Ka tó wí, ká tó fọ̀, àti ọ̀dọ́ ilẹ̀ yoruba, ati ti ilẹ̀ igbo, ati ti awọn ibi kan loke ọya ti bọ̀ soju pópó kaakiri awọn ìlú jalẹ̀ gbogbo Naijiria. Kia to mọ̀, bí ijọba ti ni ki awọn o fi awon onise abo le wọn danu ni o n le sii, pàápàá, èyí ti o waye ni Lekki, ìpínlẹ̀ Èkó, ní ibi tí ijọba Buhari to wa lórí aléfáà nigba náà ti ran soja si won, tí awọn onitohun si si ina ibọn bole, ti oku n sun lọtun, losi. Emi. tí awọn kan ni o sonu le ni ọgọọrun. Eyi lo tun wá bu bẹntiróólùù sí wahala naa. emi to sonu, ati awon dukia to sofo jẹ́ ohun ti Naijiria o tii bọ́ nínú rẹ̀ di oni yìí. Eleerú sun'gi gan an ni.

Lára awọn tí ibọn ba nibi iwọde 'end SARS' ni Lekki, ipinle eko ni oṣù kẹ́wàá ọdun 2020


Ìrírí ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún 2020 yíí ló n wá n gbé awọn ònwoye lọkan bí awọn kan tun ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní polongo iwọde tí wọn n gbero fun ọjọ́ kííní oṣù kejọọ to n bọ̀ yìí gbé lọkan soke.
Ṣé ka má paró, awọn ọmọ Naijiria n jẹ pọnmọ̀-pọnmọ iya pẹlu bíí ọ̀rọ̀ ajé ṣe polukumusu labẹ́ ijọba Tinubu. Ohun gbogbo lo gbowo lori ti a ti gbaye wa di ohun ìnira. Ohun tí awọn eeyan fẹ wọde le lori niyìí.


Amọ́, bí ipolongo ìwọde yi tii n ran kalẹ̀ bí ina ori pápá ni ijọba náà n le fùrùkọkọ pé bí awọn oluwọde o ba ni wọn kun, awọn naa o ni gba a laabọ̀. Níti Ààrẹ Tinubu, botilẹjẹpé o gba pe araalu ní eọ labẹ ofin lati ṣewọde, sugbọ́n ijọba òun ò ni gba kí ẹnikẹ́ni o ṣe jagidijagan.

Aàrẹ Tinubu kilọ̀ fún awọn olupolongo iwọde tí wọn n gbero


Lẹ́hìn ọ̀rọ̀ Ààrẹ, Ọ̀gá Ọlọ́pàá patapata náà ko sai ko ìhalẹ̀ bolẹ̀ pe ọlọpàá kò ní fi aayè gba ìwọ́de kankan nítorí kìí bimọ ire fun orileede yí.

Ọ̀gá Ọlọ́ọ́pàá ilẹ̀ Naijiria, Alagba Ẹgbẹtokun ní ileeṣẹ Ọlọọpàá ò ni faayé gba iwọde to n bọ̀

Níti ileesẹ́ ààbo ilẹ̀ yìí, ìwọ́de tí o n lọ lọ́wọ́ ni orleede Kenya ni awọn to n polongo iwọde ọjọ́ kìnní oṣù kẹjọ n fara wé. Bẹ́ẹ̀, kìí se pe iwọde ọ̀ún ko bimọ ire fún orileede Kenya nikan ni, ile oun ko tii rojutu si ọ̀rọ̀ to wà nílẹ̀ ní ìlu ọ̀un. Nítorínáà, ileeṣé aabo ilẹ̀ yíí o ni faaye gba ìwọ́de kankan rara.

Ọ̀gagun Christopher Musa, olorii ileeṣẹ́ ètò àbò ilẹ̀ Naijiria ni awọn o ni faaye gba iwọ́de, nitorí ko ni bimọ ire.


Àmọ́ bí iléeṣẹ́ Àarẹ, ileeṣẹ́ aabo ati awon ọlọpaa ti ṣe ikilo tó fun awọn to n polongo iwọde yi too, kaka ko rọ lara ewe agbọn, nise ló n le sii ni. Awọn wonyi ni, ijoba i baa pariwo ju bẹ́ẹ̀ lọ, ariwo aja lasan ni, iwọde ojo kinni oṣù kẹ́jọọ kò ní sai waye.
Bí ìwọde yìí bá waye bí awọn olupolongo rẹ̀ ti n gbero yìí, pẹ̀lú ìkìlọ̀ ijọba kí àwọn wọnyí ó ja wo, n jẹ́ elééré kò tún ní sungi lorileede Naijiria bayii, bíi ti oṣù kẹ́ẹ̀wá ọdún 2020.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *