ADÁJÓ SỌ GÉNDÉ ỌKÙNRIN MÉTA SÍ Ẹ̣̀WỌ̀N GBÉRE NÍTORÍ WỌN FI IPA BÁ OBÌNRIN ADITÍ SÙN NÍ ÌPÍNLẸ̀ KEBBI.
Lati Ajíbọ́dẹ Sekinat Ọmọbọlanle pẹ̀lú àtúnṣe lati ọwọ́ Arowoogun Abiola Ade-Ire

Ní ọjọ́ Ọjọrú tó kọjá yìí, ni Adajọ àgbà Shamsudeen Jafar ti ilé-ẹjọ gíga ìlú Kebbi dá ẹjọ ẹ̀wọ̀n gbéré fún àwọn arákùnrin mẹta kan, tí orúkọ wọn ń jẹ; Amiru Sani, Aliyu Umar, ati Bashar Dan-Inno tí wọn wá láti abúlé Wararin Zaromawa, fún ẹ̀sùn ìfípábánilòpọ̀.


Kìí kan ṣe pé àwọn òdarán wọnyí kàn fi ipá bá obinrin sùn nìkan ni, ẹni to ni ìpèníjá ara ni wpn dipanpa hùwà nlaabi naa sí. Ọmọbìnrin adití kan tí ń ṣe ọmọ ọdún méjìdínlógún ní Ìpínlẹ̀ náà ni wọn jọ dimọ ba lopò pèlú ipạ̣
Gégébí ìgbéjó,̣ìṣẹ̀lẹ̀ ibi yìí ṣẹlẹ̀ ní Wararin, abúlé Zaromawa ní ìjọba ìbílẹ̀ Gwandu ti Ìpínlẹ̀ Kebbi.


Gẹgẹ́ bí agbẹjọrò, Faridah Muhammad ṣe sọ, ó ní àwọn arákùnrin náà fi ipá bá arábìnrin náà lòpọ̀ nígbà tí ó ń sùn lọwọ́.

Ó ní àwọn ọkùnrin òdaràn métạyìí déédé já wọnú ilé arábìnrin yìí nígbà tí ó ti sùn lọ, wọn fi aṣọ tó nípọn fun ní ọrùn, wọn sì so ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú okùn kí wọn tó fi tipátipá ba ní àjọṣepọ̀ ní ọkàn-o-jọ̀kan gẹgẹ́ bí arábìnrin náà ṣe sàlàye pèlú ọnà ìbánisọrọ àwọn odi. Adajọ kò sàì kọminí sí irú ìwà ibi yìí ní ìlú tó ní ọba àti ìjòyè, tí ó sì ní òfin. Ẹ̀rú kò tilẹ̀ bà wọn rárá. Bèé, obìnrin odi yìí wà nílé ọk.ọ́
Adájọ ọún nínú ìdajó rè sọ pé, gbogbo ẹ̀rí tó dájú ṣáká ni agbẹjọ̀rò olupẹjọ ti ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn arákùnrin mẹta náà gbìmọ̀pọ̀ ṣiṣẹ́ ibi náà ni. Nítorí náà, wón jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọn fi kàn wón, nítorí náà, ilé-ẹjọ́ kò ní ohun mìíràn láti ṣe, àyàfi kí wọn fi ìyà tí ó tọ jẹ́ ẹni tí ó bá ṣẹ̀ sí òfin orílẹ̀ èdè. Nítorí ẹlẹṣẹ̀ kan, kò ní lọ láìjìyà. Nítorí eyí, ẹ̀wọ̀n gbéré ni won da fún awọn ọdaran náà ní ìbámu pẹlu Òfin ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ kóòdù 256 àti 60 ti ń bẹ ní Ìpínlẹ̀ Kebbi, ti ọdún 2021”
Ní èrò ilé iṣẹ wa, ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ yìí tọ sí àwọn ọ̀daràn yìí nítorí ẹranko tí ó ń fi àwọ̀ ènìyàn bora lásán ni wọn. Eléyìí yóò sì kọ àwọn ará ìyókù lọgbọn tí wọn ń gbìmọ̀ láti ṣiṣẹ́ ibi náà.


Àti wí pé ìbèrù Ọlórun ṣe kókó nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe. Àwọn arákùnrin yìí kò ti ẹ̀ bẹ̀rù bóyá, obìnrin adití náà lè gbé ẹ̀mí mì nígbà tí wón ń ṣiṣẹ ibi náà. Ẹ̀mí ọmọlàkejì wọn kò jẹ wọn lógún rárá.
Àtunbọ̀tán ohun gbogbo ló yẹ kí a má a rò, kí a tó ṣe ohunkohun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *