ÈDÙMÀRÈ GBÀ WÁ O; ÀWỌN FULANI ADARANJẸ̀ KỌLU ÀWỌN ÀGBẸ̀ NI PLATEAU NITORÍ WỌN Ò GBA ÀSẸ KI WỌN TÓ WỌ OKO
Lati owo Omobolanle Sekinat Ajibode.


Àwọn agbébọn adaranjẹ̀ tí wọn fura sí kan ni iroyin sọ pé wọn ti kọlu àwọn àgbẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Plateau tí awọn mẹrin sì fara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù náà.


Ohun tí a gbọ ni pé, àwọn èèyàn yìí wà lọrí oko wọn ní agbègbè Bauchi, ní ìjọba ìbílẹ̀ Riyom nígbà tí àwọn agbébọn Adaranjẹ̀ náà déédé yọ jìà tí wọn sì kọlù awọ́n tí wọn siṣé jẹjé lori oko won, tí wọn sì ṣe awọn agbẹ̀ ọún leṣe gidigidi.


Ààrẹ ẹgbẹ àwọn ọ̀dọ Berom tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ Solomon Mwantiri tó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn oníroyìn ní ìlú Jos sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ọ̀sán ọjọ ìṣẹ́gun àti wí pé àwọn tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn lọwọlọwọ.


Gẹgebí ọ̀rò Ọgbeni òún, ̣̣“nǹkan bíi agogo méje irọ̀lẹ ní ọjọ kẹfà, oṣù kẹ̀jọ, ọdún 2024 ni àwọn Agbebọnrin ọ̀ún tí wọn jé èyà ̣̣Fúlàní tó lé ní ogún (20) pèlú ̣àwọn ohun ija olórón kọ lu àwọn àgbe tí wọn je ọmọ bíbí ìlú Lwa ní agbègbè Bauchi, ní ijọba ìbílẹ̀ Riyom tí wọn ń ṣiṣẹ ní agbègbè abúlé Seheg. Lẹyìn ìkọlù náà, àwọn ènìyàn mẹrin ni wọ́n ní ìpalára ní ọkàn-ò-jọ̀kan.


Ọ̀kan nínú àwọn to farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ń ṣe Caleb Bachen sọ̀rọ̀ nínú ìnira tí ó wà nílé ìwòsàn pé, “ Mí ò sí ní agbègbè ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣùgbọn mo ń gbọ igbe àwọn àgbẹ̀ tí wọn ń ké gbàjarì fun ìrànlọwọ nínú ìjàmbá tí wọn wà, tí ìbọn sì ń ró lákọ lákọ.
“Mi ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, nígbà tí mò sì gbìyànjú láti sá lọ sílé ni àwọn kan lára ​​àwọn agbébọn adaranjẹ̀ tí wọn ní ohun ìjà lọwọle mi tí wón sì ṣe mí ṣíbaṣìbo ládúrú ẹ̀bẹ̀ tí mo bẹ̀ wọn.
“Mo kígbe fún ìrànlọwọ sugbọn ti n ko r'eni yoju. Ọpẹlọpẹ́ ọkùnrin kan tí ó ń jẹ Suddau ni ó gbà mí lọwọ àwọn aṣebi náà tí wọn ju mẹẹ̀dógún lọ.


Ẹlòmìràn nínú àwọn tí ó fara naa sọ̀rọ̀ pé, “àwọn gba àṣẹ lọwọ́ àwọn Fúlàní ni oṣù bíi díẹ̀ sẹ́yìn kan, kí wọn tó ṣiṣẹ́ ní oko lẹyìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọn kò ti jẹ́ kí a ṣiṣẹ́.

Àmọ́ síbẹ̀, àwọn Fúlàní yìí tún bẹ̀rẹ̀ ìhalẹ̀ wọn ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá pé, àwọn kò ní jẹ́ ká ṣíṣe lóko àwọn gbádùn ní ọdún yìí”.


“Nígbà tí a wà nínú oko wa, ni mo rí àwọn Fúlàní bíi ogún tí wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn kíkankíkan. Nigba tí ọwọ́ wọn bà wá tán, wọn bẹrẹ di ni na wá ní àlùbámi tí àwọn kan sì fara pa yánayàna tí ó jẹ pé ilé -ìwòsàn ni a padà lajú sí”.


Ìgbìyànjú àwọn akọroyìn láti kan sí agbenusọ fún Gómìna ìpínlẹ̀ Plateau jasi pabo bi okunrin oun ko gbe aago.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *