Alàgbà Délé Mọmọdù, ogbóntagìrì akọ̀ròyìn àti òṣèlú nílẹ̀ Nàìjíríà ti kọ lẹ́tà kan sí Ààrẹ Tinubu nínú èyí tí ó ti sọ kògbákùngbe ọ̀rọ̀ sí Àarẹ loríi bí ohun gbogbo nípa ètò ọrọ̀ ṣe pólúkúmuṣu.
Bótilẹjẹ wípé ẹgbẹ́ òṣèèlú alátakò ni Ọgbẹ́ni Mọmọdu wà, àmọ́ alagba oùn ní ohun tó pa oun pọ mọ́ aarẹ Tinubu ju ohun tó ya wọn lọ ni oún ṣe kọ lẹ́tà náà sí ààrẹ láti sín in ní gbẹ́ẹ́rẹ́ ìpakọ́ loríi bí ohun gbogbo ṣe rí l'Orileede yìí. Bẹ́ẹ̀, òótọ́ ọ̀rọ̀ pọ́nbelé ni ohún sọ.
Ní àkókó, Mọmọdu kọmínú sí bí awọn abẹ́sinkawó tó rọ̀gbà yí Tinubu ka ko ṣe sọ otitọ loríi bí nkan ṣe rí gan, pe won n fi tọ́rọ́ lẹ kóbò lójú fún aarẹ̀ tí wọn ò sì jẹ́ kó mọ bí nkan tí ríí gan.
Dele Mọmọdu ati Aàrẹ Tinubu
Mọmọdù ní ọ̀rọ̀ ajé nàìjíríà ti subú lulẹ̀ gbẹrẹgẹdẹ nítorí ṣe ni Tinubu n fi owó tó yẹ kó gbé ọrọ̀ duró sòfò dànù.
Lára ohun tí Mọmọdu ni aarẹ́ súnwó nina lé lórí ni ọkọ̀ bàálù míràn fún àarẹ, pínpín owó ìranwo lainí etò tó gúnmọ́ àti awọn ìnákúnàá yòòkù tí ijọba n ṣe káàkiri.
Mọmọdu kò sàì wá gba ààrẹ nímọràn àwọn ohun tó yẹ ko ṣe kí ohun igba o lè tun san ilẹ̀ yí. Lakọkọ, aarẹ gbodo sagbelarugẹ fun idanilekọọ imọ isẹ ọwọ́ fún awọn ọ̀dọ́. Bẹ́ẹ̀ si ni ki ijoba o mojutó àwọn ilẹ ẹkó gíga. Béè sì ni ijọba gbọdọ̀ mójútó ètò ọ̀gbìn ìgbàlódé.
Lórọ̀ kan sa, Mọmọdu ní Àarẹ Tinubu gbọ̀dọ̀ jáwọ́ niná owo àjọni oríléèdè yí ní ìnákùnàá.