Lóbátán! Gómínà Yahaya sọ pé ìpínlẹ̀ Gombe kò lè san ₦70,000 owó oṣù tó kéré jù fún àwọn òṣìṣẹ́.
Lati owo Ajibode Sekinat Omobolanle

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Gombe tí ń ṣe Inuwa Yahya ti sọ ọ di mímọ̀ pé Ijoba oun kò lè san owó oṣù tuntun tí ìjọba ni kí àwọn san fún àwọn òṣìṣẹ, ìyẹn ₦70,000. Tí ó sì fura pé kì ń ṣe ìlú àwọn nìkan ló ń dójú kọ ìṣòro àti san owó yìí.


Alága àwọn Gómìnà Àríwá tí ń ṣe Ọ̀gbẹni Yahaya, sọ̀rọ̀ ní ìpàdé tí wọn ṣe pẹ̀lú àwọn olùdarí òṣìṣẹ, àwọn ẹgbẹ àwùjọ àti àwọn ẹgbẹ oníṣòwò ní ilé Ìjọba ní Gombe láti jíròrò nípa ìwọde ẹ̀họnú tí àwọn ará-ìlú fẹ ṣe.


Ó ní ètò ìpínfúnni láti inú àpò ìjọba kò tó nnkan, èyí ló sì fàá tí àwọn kò lè fi san àfíkún owó oṣù tuntun. Bí ó ti lè jẹ́ pé, owó ìpínfúnni fún Ìpínlẹ̀ Gombe àti àwọn ìpínlẹ̀ tó kù ti lékún si gẹgẹ bí Ààrẹ Bola Tinúbú ti kéde dídín owó ọ̀wọnlọwọ̀n èpo kù.


Gòmìnà oun ninu oro re so pé nítorí ìdí èyí, oun “ ò lè san owó oṣù tó kéré jù tí ń ṣe ẹgbèrún lọnà àádórin náírà(₦70,000), kìí sì ṣe Ìpínlẹ̀ Gombe ló ń dojú kọ ìṣòro yìí”. Ó ní kó dá, àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn ṣì ń tiraka láti san owó oṣù ti tẹlẹ̀ tí ń ṣe ₦30,000 ni àmbèlètàsé owó oṣù tuntun yìí.


Gómìnà náà tún sọ pé, àwọn kò tíì gba ìrẹsì ogún (20) ọkọ̀ ńlá tí ìjọba àpapọ̀ ṣe ìlérí fún àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan láti dín ebi àti ìyà àwọn ará ìlú kù.
Ọ̀gbẹni Yahaya tún sọ pé bílíọ̀nù méjì náírà péré ní Ìpínlẹ̀ Gombe gbà tí ó yàtọ̀ sí bílíọ̀nù márùn-ún tí ìjọba àpapọ̀ fún àwọn ìpínlẹ̀ tó kù.


Gómìnà Yahaya rọ àwọn ará ìpínlẹ̀ náà láti yàgò fún wàhálà kí wọn dáwọ́ ìwọde ẹ̀họnú wọn dúró láti jẹ kí àlàáfíà jọba ní ìlú àwọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *