OWÓ ÒṢÌṢẸ́ TÓ KERE JÙ TUNTUN ATI ỌRỌ̀ AJÉ ILẸ WA

Yoruba bò, wọn ni ohun tí n bẹ lẹyìn Ofa ju òjé lọ. Asamọ yí ló n toka sí owó òṣìsẹ́ tuntun tí Aare Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́ lù.
Ní ọjọ́bọ̀ ọjọ́ kejidinlogun oṣù kèje tó kọja yìì mi Aarẹ buwó lu ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà bí owo oṣìṣẹ́ tó kere jù. Ohun tó dani loju ni pé, inu awọn òsìsẹ́ yóó dùn sí ìgbésè yíì bó ti ẹ̀ jẹ́ pé iye owó tí wọn fẹ́ bí owó òṣììṣẹ́ tó kéré julọ gbẹnu sókè ju aadọ́rin naírá lọ.


Ẹ ó rántí pé Àarẹ ti buwọ lu aadọrin naírà bí owó òṣìṣẹ́ tó kere ju. Ohun tó kù ni ki ilé igbìmọ asofin lati buwọ lu àádọ́rin náírà oùn. Bẹ́ẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ náà ti fara mó iye owó tuntun òún.

Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Aṣofin ilẹ̀ wa

Àmọ́ sá, òrò tó wà nílẹ̀ yíì, bí a ò bá fi ọgbọ́n ṣe e, kàkàkí ó mú ayò wá, àfàìmọ̀ kí ohun gbogbo ó má tún polúkú musu íi nígbà tí ọrọ̀ ajé wa ba tún subú lulẹ̀ síi, tó ya délè bí owó aṣọ fún àwọn ìdí pàtàkì kan wa tó lè ba nkan jẹ́, a fí tí ìjọba bá tete saáyan láti ma jẹ kí ẹ̀kúnwó fún awọn òṣììṣẹ́ yìí o ma ba nkan jẹ́ mọ́ ọrọ̀ ajé oríílèèdè yí lára.


Ìdí kìíní tí ẹ̀kúnwó yìí fi le ba nkan jé mọ́ wa lára ní pé bí awón ọlọ́ja ba ti le gbọ́ pínrín pé wọn ti fi owó kun owó awọn oṣiiṣé ní awọn naa o fi owó kun owo ọja láà b'èṣù b'ẹ̀gbà tí ohun gbogbo yio tun won gógó ju boti wà báyìí lọ. kí èyí má baà rí bẹ́ẹ̀, ìjọba gbọdọ gbé òfin sílẹ̀ lorí òte tí owó gbogbo ọjà máa jẹ́ lati dekun awon elérè àjẹpajúdé ti maa kóbá ọrọ̀ ajé.

Àwọn àjọ òṣììṣẹ́


Idí míràn ẹ̀wẹ̀ tí ẹ̀kúnwó òṣììsẹ́ fi le s'àkóbà fún ọrọ̀ ajé ni ti awọn ileesẹ́ àdani tí awọn naa ní awọn osiiṣẹ́ tí wọn n sanwo fún sugbon ti ẹ̀kúnwó yíì ò dé ọ̀dọ ti won, awon ajọ osiiṣẹ́ ti won naa le bẹ̀rẹ̀ sí ní f'apá jánú. Bí wàhálà bá wá pọ̀jù tí wọn bá fi le fi agidi mú àwọn iléesé àdáni láti fi owó kún owó oṣììsẹ ti wọn náà, wọn kò ní sàì fi owó kún awọn ohun ti wọn n pèṣè jáde, èyí kò sì ní sàì fa ọ̀wọ́ngógó ọjà. Èyí kò sì ní sàì fi kún wàhálà tí ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yíí n là kọja lọwọlọwọ.


Ka máá da ara wa lágara, ìjọba gbodo mojutó bí ẹ̀kúnwó owó oṣù òṣiṣẹ́ tuntun tí Aàrẹ Tinubu búwọ́ lù kò ṣe ní ba nkan jẹ mọ́ ọrọ̀ aje ilẹ̀ wa lára.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *