Yorùbá bọ̀, wọn ní bí kò bá ṣe ni rí, a kìí ṣọ pé ó tún dé. Àṣamọ̀ yí ló dálé orí ìfẹ̀hónú han ọjọ́bọ̀ tó kọjá yìí tíí ṣe ọjọ́ kinní oṣù kẹ́jọ tí awọn ọmọ orileedè yí jade láti wọde lorí bí gbobo nkan ṣe polúkúmuṣu ní ilẹ̀ yìí.
Ṣe ogun àwítẹ́lẹ̀ kìí pa arọ tó ba gbọ́n, láti ìgba tí awọn ènìyàn kan ti kéde ọjọ́ iwọde yìí ni ijọba àti awọn alátìlẹ́yìn wọn ti n sakitiyan kí iwọde yìí ma baà wáyá tabí ko ma baà f'ese múlẹ̀. Bí Àarẹ Tinubu ti n parowa to, ti awon olọpàá n halẹ, tí awọn alatìlẹyìn ijọba náà n polongo takọ iwọde yìí, síbẹ̀, ó papa wáyé.
Ṣe kìí dé báni ká yẹrí, nígbà tí ijọba ti ri pé iwọde yìí ko se pa mọ́lẹ̀ ni wọn ti da awọn ọlọ́pàá dìgbòlùjà síta, pàápàá, ní awọn ìlú tí nkan ti le le daindain bíí Ìlú Èko, Abuja, Kaduna, Kano, Ibadan, ati gbogbo olu-ilu ìpínlẹ̀ jakejado Naijirià. Idi tí won fi ṣe eyi ni kí nkan má baa bajé mọ ijọba lara.
Amọ́ síbẹ̀ náà, eleeru pàpa sungi naa ni. Se wọn ní erépá kìí bímọ ire, bí ò bí kùmọ̀, a sì bí kondó, béè ni ọrọ ọ̀un ríí, nítorí, ìwọ́de ọ̀un bi ìgè, ó sì bí Àdùbí. Bí o tilẹ̀ jẹ́ wípé iwọde ọun bẹ̀ẹ̀rẹ̀ wọ́rọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ ní ọwọ́ àárọ̀, sugbọn nígbà tí yo fi di ọwọ́ ìyálẹ̀ta mọ́ ọwọ́ ọ̀san, gbogbo rẹ̀ ti n gbóna janjan Tí nkan sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yan káàkiri. Bí ẹmi ti n sofo ni dukia oniyebiye n bajẹ́ tí awọn kan si n fi asiko ọun jale kiri.
Ní ìpinlẹ̀ Kano ni o dabii pé nkan ti yan ju. Nise ni awọn olùwọ́de n kọlu ileese ijọba kaakiri ti wọn si n bajẹ́. Boya eyi ni awọn ọlọ́pàá n gbiyanju láti dawọ ẹ̀ duro to fi di ohun tí wọn n yinbọn kaakiri ti ẹ̀mi si ti bẹ̀ẹ́ sofo.
Bí awọn olùwọ́de ọun ti n kọlu ileese ijọba ni wọn n fọ ti awọn aladani ti wọn si n kó wọn ni nkan lọ̀. Kódà, ohun ti ó bajẹ́, ní ìpínlẹ̀ Kano ní tẹmi ati ti ara bùáyà.
Ní ipinlẹ̀ Niger, emi to sòfò ko din ni méwàá, ohun to ti ẹ̀ wa dùn yan níbẹ̀ ni pe awọn ti ko ti ẹ̀ wa kopa rárá ninu iwọde sugbọn tí wọn n lọ jẹ́jẹ́ wọn ni ibọn ọlọpàá pa jù ni ìpìnlẹ̀ Niger. Ní Suleja nikan, awọn ti wọn da ẹ̀mi wọn legbodo lé ní mẹfa tí àìmọye si farapa yanna yanna.
Ní ìlú Abuja ẹ̀wẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wipe iwọde wayé, amọ, ìroyìn agbọ-sọ-gbá-nù ò tibẹ̀ wá nitorí awọn ọlọpa to bọ̀ síta o dí awọn olùwọ́de lọwọ́ tí awọn onitọhun náà o sì kọjá ààyè wọn. Bi o tilẹ̀ jẹ́ pe awọn ìwà ipa kan ṣele.
Ni ipinle Katsina, ohun tó yani lẹ̀nu ni pé awọn olùwọde lọ gbé iwọ́de ká Ààrẹ Oríléédè ilẹ̀ yí àná, Ògágun-fèyìntì Muhammed Buhari mọ́le n, nítórí, adugbo ẹ̀ gan ni wọn fi se ibi ìwọ́de wọn. kódà, ohun tí a gbọ́ ni pe wọn dáná sun awọn ilé kan ni ẹ̀gbẹ́ ilé Ààrẹ ana ọun.
Ilé awọn Olùwọ́de dána sun ladugbo Buhari
Ní ìpínlẹ̀ Eko ẹ̀wẹ̀ tí a ti ro pé nkan yòó bajẹ́ gan ni, nkan o fi gbogbo ara bajẹ́. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ́de waye kaakiri pàápàá ní Ọjọta ati Lekki, ko sí iroyin ẹmi to sọnu. Biotilẹ je wipe nkan fẹ́ẹ̀ bajẹ ni Lekki Toll gate nigba tí awọn ọlọ́pàá n fi ibọn tajutaju le awọn onwọde seyin, sibẹ̀, eṣu ò ja Ijọba gba.
Gende okunrin kan re e ti n wode ni ihoho ni agbegbe Ojọta, Ipinlẹ̀ Ekó.
Lẹyìn ohun gbogbo sá ní ọjọ kínní oṣù kẹ́jọ, eleeru tùn pàpà sun'gi nigba ifehonuhan tako ebi ati ijọba oṣi ní Naijiria, ẹ̀mi aráàlu sọnu rẹbẹtẹ, bẹ́ẹ̀ si ni awọn ọlọpa o fara ire lọ, tí dukia orisirisi to je ti ijọba ati ti araalu naa si sofo, lai lonka.
Oloopa tó fara pa lasiko iwọde