Ọ̀PỌ̀ OLOṢELÚ NÀÌJÍRÍÀ LÓ TI GBÉ’ṢÙ MÌ – ỌBA OLÚGBỌ́N KẸHÙN SỌ̀RỌ̀


Ọba Olúgbọn ti ìlú Orílè-Igbọ́n tí ó wà ni ìjọba ìbílẹ̀ Surulere ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ní ìṣesi ọ̀pọ̀lọpọ oloṣelu ilẹ̀ Naijiria fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn lo ti gbe eṣu mi ní bí wọn ṣe maa n se ni gbara tí wọn ba ti dé orí àléfà.


Ọba Olúgbọ́n sọ̀rọ̀ yí lásìkò to n gba olórí ijọ Kérúbù àti Sérafù Onítèsíwájú Ayò Ni o ní gbogbo àgbáyé, Ẹni Ọ̀wọ̀ Bàbá aladura Abiodun Àlògbó àti awọn asoju ijọ ọ̀un míràn ní alejò ní aafin ní ọjọ́ kẹta oṣu kewaa tó kọjá yìí.

Ẹni Ọ̀wọ̀, Baba Aladura Abiodun Alogbo, Olorí ijọ Kerubu ati Serafu Onitesiwaju Ayo Ni o ni gbogbo agbaye


Ọlugbọ́n kọminu sí bí ohun gbogbo ti ṣe polukumusu ní oríléèdè yí tí àwọn oloṣelu si n ṣe ise ẹni àmọ̀rí ì báà kú tí wọn se dé fìla gbèsè-ò-kàn-mí sí gbogbo ohun to n sẹlẹ ní ilẹ̀ yí. Ọba ọun ní ipò tí Naijiiria wa bayii jẹ́ ipò tí ó ba ni ninu jẹ́ bí ohn gbogbo ti wọn bi ojú tí ko si aabò ní ibikibi, bẹ́ẹ̀ awọn ìjọba lo sún wa dé ibi tí a wa yi.


Ọba Olugbọn wa fi asiko igbalejo oun fi àìdunu rẹ̀ han síi bo seje wipe àwọn olori esin naa n darapọ̀ mọ awon oloselu lati ba ilú je. Ọba oun ni o ba ni ninu je pe ife owo ọwọ awon oloselu ti awon olórí esin n gba ko jẹ́ kí wọn o le sọ otitọ fun awon oloselu, bẹ̀ẹ́ ojuṣe àwọn olorí ẹsìn ni láti máa tó àwon araalu ṣọna rere ní ṣíṣe. Ọba alaye ọun wa ro awon olorí esin lati ji ìjí òdodo sí ojúṣe tí Ọlórun fun wọn. Bíbéèkọ, ìdájọ́ Ọlọrún ko ní pẹ́ ẹ dé. Ọba alayé ọun kò sàì wá kìlọ̀ fún àwọn oloṣelu náà kí wọn yípadà kúrò nínu ìwa ìkà wọn si awon araalù nitori idajọ tí wọn náà n bọ̀.


Àmọ́ Ọba Ọlugbọn fi asiko ọ̀ún lu ijọ Kerubu ati Serafu Onitesiwaju Ayo Ni o lọgọ̀ọ́ ẹnu bo ṣe jé wípé ìjọ ọ̀un tayọ laarín awọn ijọ alaṣọ funfun, tọ́ sì jẹ́ pé ijọ ọ̀ún ko rẹ̀yìn nínú iṣẹ́ ìhinrere tí Olúwá pe gbogbo Onígbagbọ sí. Bẹ́ẹ̀ si ni ijọ ọun n gbiyanju nínu iṣe rere ní ṣíṣe. Ọba ọ̀un wá dupẹ lọwọ ijọ ọ̀un fún awọn iṣé ìdàgbàsoke tí wọn ti ṣe eyí tí o ti mu ìlu Oríle-Igbon tẹsíwáju, béè ni ọba ọ̀ún wá ṣèlérí ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọ ọ̀ún nínu akitiyan itesíwáju idagbasoke wọn.


Nínu ọ̀rọ̀ olorí ijọ Kerubu ati Serafu Onitesiwaju Ayo Ni o, Ẹni ọ̀wọ̀, Wòólì Abiodun Alogbo dupẹ lọwọ Olúgbọ́n fun bí Ọba alayé ọ̀ún ṣe gba oun ati awọn aṣojú ijo yooku lalejo. Olorí ijọ ọ̀un ko saì wá ṣèlérí pé àwọn yóó tesiwaju ninu awọn ìṣe rere tí o ya ijọ Kerubu ati Serafu Onítèsíwájú Ayọ Ni o sọtọ̀ nínu àwọn ijọ aláṣọ funfun, eyí tii ṣe igbe aye onigbagbo bí bíbelì t ṣe alakalẹ rẹ̀ àti mímú iṣẹ́ ìhìnrere ní ọ̀kúnkúndùn.


Lara awọn aṣojú ijọ ọ̀un tí wọn bá Baba Aladura Alogbo kọwọrìn lọ ààfin Olugbọn ni Akọwé àgbà ijọ ọ̀ún ní àgbáyé, Wòólì Oluṣẹsan Anthony Samaye àti àwọn asojú ijọ ọ̀ún miran.

Akọwé àgbà ijọ Kérùbù àti Séráfù Onitesiwaju ní gbogbo Ayo Ni o ni àgbáyé, Wòólì Oluṣẹsan Anthony Samaye pẹlu Baba Aladura ijọ ọ̀ún

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *