Yoruba bo, won ni “ai le ja ni ile baba mi o debi, ojude baba eni kii gbeja eni”. Asamo yi gan an lo ba idije to kangun si asekagba laarin Super Eagles Nigeria ati Bafana Bafana ile South Africa mu regi.
Idi ni pe erongba awon eeyan ni pe bi o ti je wipe alaga ajo ti n se kokari ere bolu nile Africa, CAF, iyun, Alagba Patrice Motsepe se je omo ile South Africa, afaimo ni ki eyi o mo je waala fun Super Eagles lati bori idije oun.
Awon eeyan so ipa ti okunrin oun nko bi o ti n fara so pe orileede oun ni oun fe ko maa bori sa. Idi ti awon eeyan fi so eyi ni pe Alagba Motsepe yi kii lo woran gbogbo idije, amo, gbogbo eyi ti orileede re gba pata lowo. Awon onwoye so pe iru nkan bayii le fa ki awon oludari idije o mo beeru lati se bo se to ninu idari idije oun. Koda, iwe iroyin kan nile Morroco f’esun kan alagba oun pe Refiri se ojoro gbe Bafana Bafana ninu idije ti won gba ni won fi fi eyin Morroco na ile wi. Nitorina, eru maa n ba awon orileede to ba fe koju Bafana Bafana ninu idije AFCON to n lo lowo.
Omowe Patrice Motsepe, alaga CAF ti n lo ipo re lati sojoro fun orileede re.
Amo sa o, Super Eagles fi ye Bafana Bafana pe bi ale baba eni ba ju iya eni lo, iya laa pe e ni bi won se din dundun iya fun Bafana Bafana je ninu idije to kangun si asekagba to waye lojoru ojo keje osu keji odun yi loju Motsepe baba won.
Looto, awon adaari idije fe e lo awon ogbon ayinike lati re iye eye Super Eagles ko mo le fo, amo, won so ada s’ikun lasan ni, eran lo, ada won tun sonu. Iya meji wa a je oku igbe won. Lakoko na, won ko lati ka golu Osimhen.
Osimhen kawo l'eri bi Refirii ti ko lati ka goolu to gba wole
Leekeji ewe, Refirii ati awon oludari ere yooku o f’aye gba penariti to ye ki won fun agbaboolu to wole fun Osimhen. Lori kini? Tori orileede ti alaga CAF ti wa ni Super Eagles n ba na an tan bi owo.
Jose Peseiro, Akoni-mogba Super Eagles naa pariwi bi Refirii se so penariti di firikiiki mo Super Eagles lowo pelu ojoro
Amo o, leyin gbogbo re sa, Super Eaggles gbeye lowo Bafana Bafana ni bi won ti re won lepa ninu Panariti to yori si amin merin si meji; 4-2. Ni super Eagles ba peregede fun asekagba nibi ti won o tin a an tan bi owo pelu Ivory Coast.
Egbe Agbaboolu Ivory Coast to fe gbena woju Ekun Nigeria ni asekagba